HapMap Project logo
Asepọ HapMap ti Gbogbo Agbaye
 

Ibusọ | Nipa Asepọ | Esi | Itẹjade | Tutorial |

中文 | English | Français | 日本 | Yoruba

Nipa Asepo HapMap ti Gbogbo Agbaye

Idi ti a şe gbe iwadi HapMap kalẹ ni lati şe ilana titun ti a le fi yẹ ohun ti o wa ninu ẹjẹ ọmọ eniyan ti o si ndari ajogunba; eyiti a npe ni Jiini, tabi ti awọn oloyinbo npe ni Gene. Ilana titun yi, yio jẹ ki a le şiwadi ti o peye lori Jiini, paapa, nipa ọna ti Jiini onikaluku fi yatọ si ara wọn. Erogba wa ni wipe HapMap yi yio jẹ ohun anfani nla fun awọn Ọjogbon ti wọn şiwadi lori ọna ti Jiini şe ndarapọ mọ aisan, ilera, tabi bi ogun orişirişi şe nba eniyan lara mu ati bẹ bẹ lọ. Gbogbo awaari ti o ba ti inu iwadi yi jade ni a o fi fun gbogbo Agbaye lọfẹ.

Awọn Ọjọgbọn lati orilẹ-ede Japan, Canada, Amerika (United States), Ilu-Ọba (United Kingdom) ati orilẹ-ede wa Naijiria ni wọn jọ nse iwadi yi [ E tẹ ikaana mọ ibi yi lati le ni imọ si nipa awọn alaşepọ iwadi yi]. Larin ọjọ kẹta si ọkan-dinlọgbọn oşu kẹwa Ọdun 2002 ni a bẹrẹ eto yi [E tẹ ikaana mọ ibi yi lati le ni imọ si nipa isẹlẹ ni awọn ọjọ wọnyi]. A si lero wipe yio gba ọdun mẹta gbako.

Bi a o ti lo HapMap yi

Ọpọlọpọ aisan ti o wọpọ larin awa ọmọ eniyan bi ẹjẹ-ruru, irẹwẹsi-ọkan, kansa, ati bẹ bẹ lọ ni wọn nwaye nipasẹ idapọ awọn ohun ajogunba ti o wa ninu ẹjẹ - Jiini - ati awọn eyi ti o wa ninu aiye, eyi ti awọn oloyinbo npe ni environment. A mọ wipe iyatọ ti o wa ninu Jiini ẹnimeji ọtọtọ (laişe ẹbi tabi iyekan) ko ju iwọn kan lọna ẹgbẹrun lọ. Amọ ọkan şoşo yi şe pataki pupọ nitori ipa ti o nko ninu iyatọ ti o wa larin awa ọmọ enia, paapa lori iru aisan ti onikaluku le ni, bi ogun ti le ba ni lara mu si, ati bẹ bẹ lọ. Imọ nipa iyatọ kan yi wulo lọpọlọpọ.

Awon kooko ibiti iyatọ wa ninu jiini ni a npe ni siniipu Single Nucleotide Polymorphisms(SNPs). Fun apẹrẹ, awọn kan a ni Jiini ti o ni 'A' ni kooko kan, nigbati awon ẹlẹgbẹ wọn a si ni 'G' ni oju kooko kanna. Nigbati a ba ni iwọn jiini ti o yatọ si ara wọn nipasẹ iru kooko ti wọn ni, iwọn Jiini bayi ni a npe ni "kooko-jiini" allele.

describes an allele
Aworan yi fi apẹrẹ kooko-jiini han

Ẹya ara ti o kere ju ni a npe ni sẹli (cell). Sẹli kankan si ni akaşu-jiini (chromosomes) mẹtalelogun. Awọn akaşu-jiini yi ni akọ ati abo. Akaşu-Jiini kẹtalelogun ti okunrin si yatọ si ti obirin. (Ẹ wo http://www.dnaftb.org/dnaftb/ fun ẹkunrẹrẹ alaye lori ọrọ yi). Nigbati a ba ri iwọn jiini ti o ni siniipu lara, a ma npe irubẹ ni ẹya-jiini. Ọna ti a ngba şe awari ẹya-jiini ni awọn oloyinbo npe ni genotyping.

Ẹgbẹgbẹrun siniipu ni o wa lara awa ọmọ eniyan. A si ma nşe ajogunba awọn kooko-jiini ti wọn ba sun mọ ara wọn. Iru iwọn jiini ti o ba ni siniipu ti wọn sunmọ ara wọn bayi ni a npe ni "iwọn-jiini" (haplotype). Iwọn-jiini ti o wa lara pupọ ninu awọn akaşu-jiini ko pọ pupọ ju, iba wọn yi si ni wọn nşe alagbọwọ iyatọ ti o wa larin awa ọmọ eniyan. Botilẹ je wipe akaşu-jiini kan ni ọpọlọpọ siniipu, awọn siniipu-alapẹrẹ (tag SNP) kankan to lati tu aşiri iru iyatọ ti o wa ninu akaşu-jiini bawọn yi.

Haplotypes
Aworan yi fun wa lapẹrẹ akaşu-jiini ati awọn siniipu ti wọn wa ninu rẹ. Ẹ o ri iwọn-jiini mẹta ninu apẹrẹ yi Awọn siniipu ti awọ wọn yatọ to fun wa lati da iwọn-jiini yi mọ. Ti a ba ri akaşu-jiini ti o ni kooko-jiini A ati T ni ojude awọn siniipu alapẹrẹ yi, irufẹ akaşu-jiini bẹ ni iwọn-jiini ti akọkọ.

Iwadi HapMap yio şe apejuwe awọn iyatọ ti o wa larin awa ọmọ eniyan. Yio si lo awọn siniipu alapẹrẹ lati mọ iwọn-jiini ti o wa, ati deede ibiti awọn iwọn-jiini yi wa lara akaşu-jiini.

Awọn ọjọgbọn ti wọn se awari lori ohunfa aisan a ma fi awọn alaisan we awọn ti ko ni aisan. Deede akaşu-jiini awon ẹgbẹ mejeji yi si le yatọ si ara wọn de bi wipe yio tu asiri iwọn-jiini ti o ni şe pẹlu aisan yi. A le sọ wipe ki awọn ọjọngbọn lọ yẹ gbogbo ẹgbẹgbẹrun siniipu ti o wa ni awọn ibi wọnyi wo lati ni imọ si nipa aisan ti wọn se iwadi le lori. Amọ iru ilana yi a na ni lowo pupọ ju. HapMap yio fun wa ni anfani a ti din inawo yi ku ni ilọpo mẹwa si ogun. Idinku yi yio fun wa ni anfani ati şe iru awọn iwadi yi dada.

Ẹya ati elo

Iye iwọn-jiini ti o wa yatọ larin ẹya si ẹya, nidi eyi, o di dandan wipe ki a şe iwadi yi ni ọpọlọpọ ẹya. A ti şe iwadi ni şoki larin awọn Yoruba ati awọn ẹya miran ni ilẹ Japan, China ati Amerika. Eleyi jẹ ki a ni oye wipe ti a ba fi awọn ẹya wọnyi na şe HapMap, yio fun gbogbo agbaye ni anfani pupọ. Idi niyi ti a fi pada lọ si arin awọn ẹya wọnyi lati ma ba işẹ yi lọ. A o lo ẹya ara ti a npe ni DNA lati ara ẹbi Yoruba ọgbọn ti ngbe ilu Ibadan. Awọn ẹya Japan, China, ati oyinbo alawọfunfun na yio si fi iru ẹya ara yi silẹ. Gbogbo ẹya ara yi ni a o gba pẹlu aşẹ ati ilana ti awọn ilu and agbole ti a o ti şe işẹ yi filelẹ. Awọn olukopa ninu işẹ yi yio si fi ọwọ si iwe ti wọn yio fi yọnda ara wọn. A o si jiroro pẹlu awọn olukopa ati awọn ara agbole wọn lati le mọ boya o ni aşa tabi ewọ kankan ti işẹ yi le tako.

Ọwọ ile-işẹ Coriell ni a o ti gba awọn ẹya ti oyinbo (http://locus.umdnj.edu/nigms/). Ibẹ na si ni a o ti şe ohun amulo lati inu ẹjẹ ti awọn olukopa ba fun wa lati awọn eya yoku. A ko ni gba imọ tabi oye kankan ti yio jẹ ki awọn ti o ba darapọ mọ işẹ yi di mimọ. A o gbe igbimọ alabẹşekele dide ni arin awon ẹya kankan ti yio mojuto işẹ yi. Wọn a si ni anfani lati mojuto ilọsiwaju işẹ yi lọjọ iwaju.

Ilana ati di ibajẹ lọwọ

Bi a ba ronu si, a o ri wipe o şeşe ki isẹ yi dibajẹ. Amọ niwọngbati a ko fi orukọ tabi ami idanimọ kankan si ara awọn ohun elo ti a gba lara awọn olukopa, a nira fun ẹnikẹni lati da esi ti o jẹ ti olukopa kan tabi imi mọ. Amọ, a o mọ ẹya tabi orilẹ ede ti awọn olukopa ti jade wa. O wa şeşe wipe ki a ri siniipu ti o wọpọ larin ẹya kan tabi orilẹ ede debi wipe a le fi da wọn mọ. Eleyi le fẹ mu ija ẹlẹyamẹya wa paapa ti a ko ba lo imọ yi ni ọna ti o tọ ati ti o yẹ. O si şeşe ki a ri awọn ti wọn yio fẹ mu iba esi soki ti ayẹwo yi yio gbe sita lati se apẹrẹ gbogbo ẹya ti iru esi yi ti wa. Lati di iru ibajẹ bayi ku, a gbero lọpọlọpọ pẹlu awọn enia to n'gbe awọn ilu ti a ti şe işẹ yi.

Ọgbọn Iwadi

Lati pari isẹ yi, a o sẹ iwadi ẹgbẹgbẹrun siniipu. Isẹ si ti nlọ lọwọlọwọ ni awọn ile-isẹ ni ilu Canada, China, Japan, Ilu-Ọba, ati Amẹrika. Nigbati işẹ yi bẹrẹ, iwọnba siniipu la ni (dbSNP). A şe akiyesi wipe ọpọlọpọ lara awọn akaşu-jiini ni ko ni siniipu, a ti wa tepa mọşẹ lati wa awọn siniipu wọnyi. A ti pin işẹ yi larin awọn ile-işẹ wọnyi (assigned chromosomes). A si mọ wipe wọn yio şe ni ẹkunrẹrẹ ati ni ọna ti o peiye. Ilana si ti wa lati ri wipe a din aşişe ninu isẹ yi ku.

Ilana iwadi

Kooko esi ti iwadi yi yio gbe jade yio jẹ lori genotype awọn eniyan ti a lo fun isẹ yi ati bi siniipu şe wọpọ si ni orilẹ ede awọn ẹni wọnyi. Ilana ti wa ti awọn Ọjọgbọn lori isẹ yi gbe kalẹ lori bi a ti şe nlo esi iru işẹ bawọnwọnyi, eleyi ni a o si lo. A si tun le gbe imọran tabi ọgbọn titun jade nipasẹ iwadi yi. Nitori wipe lọfẹ ni a o gbe esi iwadi yi saiye, awọn oluwadi miran ni anfani a ti lo esi rẹ ni ọna tiwọn, paapa ni ọna ti o le gbe ọgbọn tabi imọ titun jade. Iwadi yi yio fun wa ni imọ nipa bi sinnipu se yatọ si ara wọn si larin olukaluku, orilẹ-ede ati ẹya.

Ilana lilo esi Iwadi

Gbogbo esi iwadi yi ni a o gbe si ita gbangba fun gbogbo agbaye lati lo laisi idiwọ kankan. Awọn siniipu titun, ọna ti a fi wa wọn jade, bi wọn ti se pọ si, ati bẹ bẹ lọ ni a o gbe sita ni seke ti a ba ti mọ ọ ni ẹkunrẹrẹ. Niwọngbati a ba si nsisẹ lori wọn lọwọ sa, a o gbe ilana ti ko nira silẹ fun ilo wọn (data access policy ). Ilana yi yio wipe awọn ti wọn ba fẹ lo esi iwadi yi, ko ni di awọn Oluwadi yoku lọwọ.

A ko le ti ipasẹ HapMap yi nikan mọ nipa aisan abi ilera. Awọn Olusakoso isẹ yi ni igbagbọ wipe imọ nipa siniipu, jiini ati bẹ bẹ lọ wa fun anfani gbogbo enia ni, laisi idiwọ kankan. Bi a ba ri lara awọn Oluwadi ti wọn ri ọgbọn tabi imọ titun kan nipasẹ iwadi yi, wọn ni anfani lati lẹ ami wọn mo iru ọgbọn tabi imọ bayi, niwọngbati iru ami na ko ba di awọn Oluwadi yoku lọwọ. Awọn Oluwadi si ti jẹjẹ wipe awọn ko ni lo esi iwadi saju igbati iru esi yi yio wa fun anfani gbogbo agbaye.

Ilana bi awọn Oluwadi şe le lo esi iwadi

Awọn Oluwadi isẹ yi ko ni anfani ati lo esi iwadi (paapa eyiti o ti ikara ọwọ wọn wa) fun iwadi miran ninu Ile-Isẹ wọn niwọngbati a ko ba ti fi iru esi bayi han si gbogbo agbaye. Awọn Oluwadi ninu isẹ yi yio ni anfani lati lo esi isẹ yi ni ọna kanna pelu gbogbo agbaye ni, wọn si ti jẹjẹ bẹ.

Niwọngbati wọn ko ba ri iriri iwadi ti o ni ilo yatọ si eyiti a fi fi idi iwadi HapMap yi mulẹ, awọn Oluwadi ko da imọran lati jere tikarawọn lori isẹ yi. Amọ ti wọn ba ri ohun kankan yatọ si eyiti o ni şe pẹlu iwadi HapMap, wọn ni anfani ti ko yatọ si ti oluwadi ki oluwadi. Ki a ranti sa o, wipe HapMap ko şe iwadi aisan, ni idi eyi, irufẹ iriri ti awọn oluwadi yi ko ba ri nilati waiye nipasẹ işẹ ti o gboro kọja eyiti wọn ni şe fun igbekalẹ HapMap. Ilana ki ilana ti awọn Oluwadi ti o ba fẹ jere lori iriri ti wọn ba ri, ko ni ni anfani ati di ẹnikẹni ti o ba fẹ lo esi HapMap yi lọwọ.

Last updated : abouthapmap.html.yo,v 1.1 2004/02/06 18:09:07 krishnan Exp

Ibusọ | Nipa Asepọ | Esi | Itẹjade | Tutorial |
Ti ẹ ba ni ibere tabi asọsi, ẹ le kan si help@hapmap.org