|
Ile
isẹ mẹwa ni Japani, Ilu Ọba, Kanada, Shaina, ati ilẹ
Amerika ni wọn şişẹ lori awọn ẹya gbogbo ti a
gba. Ilana marun ọtọtọ si ni wọn nlo. A gbe ilana
kalẹ ti wọn ni lati tẹle ki işẹ wọn le ba
boju osuwọn. Wọn yio fun wa nisiniipu titun, iwọn-jiini ati
siniipu-alapẹẹrẹ, lati ara awọn igba ati adọrin
enia ti a gba ẹya lara wọn. Gbogbo esi iwadi yi ni a o gbe si ita
gbangba fun gbogbo agbaye lati lo laisi idiwọ kankan.
Awọn
Oluwadi isẹ yi ko ni anfani ati lo esi iwadi (paapa eyiti o ti ikara
ọwọ wọn wa) fun iwadi miran ninu Ile-Isẹ wọn
niwọngbati a ko ba ti fi iru esi bayi han si gbogbo agbaye. Awọn
Oluwadi ninu isẹ yi yio ni anfani lati lo esi isẹ yi ni ọna
kanna pelu gbogbo agbaye ni, wọn si ti jẹjẹ bẹ
Niwọngbati
wọn ko ba ri iriri iwadi ti o ni ilo yatọ si eyiti a fi gbe iwadi
HapMap yi mulẹ, awọn Oluwadi ko da imọran lati jere
tikarawọn lori isẹ yi. Amọ ti wọn ba ri ohun kankan
yatọ si eyiti o ni şe
pẹlu iwadi HapMap, wọn ni anfani ti ko yatọ si ti oluwadi ki oluwadi. Ki a ranti
şa o, wipe HapMap ko şe iwadi aisan, ni idi eyi, irufẹ
iriri ti awọn oluwadi yi ko ba ri nilati waiye nipasẹ işẹ ti o gboro
kọja eyiti wọn ni şe
fun igbekalẹ HapMap. Ilana ki ilana ti awọn Oluwadi ti o ba
fẹ jere lori iriri ti wọn ba ri, ko ni ni anfani ati di
ẹnikẹni ti o ba fẹ lo esi HapMap yi lọwọ.
Gẹgẹbi
a se so tẹlẹ, iwadi yi ko le gbe imọ nipa aisan jade ni
tikararẹ, amọ awọn ọjọgbọn le gbe iwadi
miran kalẹ ti yio ni irufẹ esi yi.
|