|
[A le ri ẹkọ lori ọrọ ti o jẹ mọ iboju to
olukopa ninu iwadi, asa tabi ofin
to toro mọ işẹ yi ni yi]
Ilana HapMap gbe awọn ọrọ gbankan gbankan silẹ. A
si ti mura ati petutu wọn nipa kiko awọn ọjọgbọn
ti o mọ nipa awọn ọrọ bẹ mọ awọn
oluwadi işẹ yi lati ibẹrẹ.
A o fi amin si ara DNA olukopa
ninu iwadi yi lati fi da ẹya ọmọ enia ti o ti wa mọ,
boya akọ ni tabi abo, boya obi ni tabi ọmọwọ. Amọ
ko ni si amin ti yio jeki a mọ ẹni ti ẹya yi ti wa nipato. Ko
si si ọna, ti a le fi tọpinpin eleyi, nitori wipe a gba
ẹjẹ ju iye ti a fẹ lo lọ. A ko gba akọmọna
tabi ohun ilera kankan lara awọn olukopa.
Niwọngbati ko si amin
idanimọ kankan lara ẹya ara ti a gba, ko si ewu wipe
ẹnikẹni le mọ nipa awọn ti wọn kopa ninu iwadi
yi. Amọ a le mọ ilu ati ẹya enia ti wọn ti wa [
Ilana bi a ti se gbọdọ ma darukọ awon ilu ati ẹya enia
ti a gba jiini lara wọn.] Eleyi le fẹ mu ija
ẹlẹyamẹya wa paapa ti a ko ba lo imọ yi ni ọna ti
o tọ ati ti o yẹ. O si şe şe ki a ri awọn ti
wọn yio fẹ mu iba esi soki ti ayẹwo yi yio gbe jade lati fi
şe apẹrẹ gbogbo ọmọ ẹya enia ti iru esi yi
ti wa. Lati di iru ibajẹ
bayi ku, a gbero lọpọlọpọ pẹlu awọn enia to
n'gbe awọn ilu ti a ti şe işẹ yi.
Esi iru iwadi bayi paapa le lodi si igbagbọ tabi aşa awọn
ẹya enia kankan. A mọ wipe orişi aşa ibilẹ ati itan
orisun ni o wa, esi iwadi yi si le tako lara awọn aşa tabi itan wọnyi. O si le lodi si ilana ti
awọn ẹya miran ni lati mọ tani o jẹ ọmọ
ẹya wọn.
Nipari, a le ri awọn ti
wọn yio fẹ lo esi iwadi yi lati gbe ọtẹ kalẹ
larin ẹya enia dudu ati oyinbo. Ti a ba fi oju inu wo, a o ri wipe, esi
iwadi yi lodi si gbogbo agabagebe bẹ. Kooko ti yio si fi han wa ni bi awa enia ti
şe jọ ara wa lọpọlọpọ, laibikita ẹya
tabi orile ede ti a ti wa.
Orisirisi ọgbọn ni iwadi yi gbekale lati daabo bo olukopa.
Gbogbo ẹya ara yi ni a o gba pẹlu aşẹ ati ilana ti
awọn ilu and agbole ti a o ti şe işẹ yi filelẹ.
Awọn olukopa ninu işẹ yi si fi ọwọ si iwe ti wọn
yio fi yọnda ara wọn. A si jiroro pẹlu awọn olukopa ati
awọn ara agbole wọn lati le mọ boya o ni aşa tabi
ewọ kankan ti işẹ yi le tako. Eto ijiroro yi fun awọn
ara agbole ati aba ni anfani lati kọ nipa ati lati jiroro lori gbogbo
ohun ti o jẹ mọ iwadi yi. Ilana ti a tẹle lati şe eleyi
yatọ lati ilu kan si omiran, amọ wọn da lori ipade pẹlu
awọn agba ati gbogbo abule lapapọ. A si fi ọrọ wa
awọn ara ilu lenuwo lọkankan. Eleyi jẹ ki awọn oluwadi
kọ nipa awọn ti wọn nşe iwadi le lori, o si jẹki a
ni itẹsiwaju pẹlu ibalẹ ọkan.
Ni arin awọn olukopa kakiri, a gbe igbimọ
alabẹşekele kalẹ (Community Advisory Group) ti o jẹ alarinna larin awọn oluwadi, awọn
olukopa ninu işẹ yi ati ile işẹ Coriell, nibiti a o fi
awọn ẹya ti a gba pamọ si. Igbimọ yi ni yio jẹ ki
awọn mutunmuwa mọ bi wọn ti şe nlo ẹya ara
wọn ti wọn gba si, nitori wipe, gẹgẹbi alaye ti a ti
şe si iwaju, olukaluku olukopa ko le mọ nipa ẹya ara
tirẹ, niwọngbati ko si amin ti a le fi da mọ mọ.
Amọ o şe şe wipe ki awọn ẹya kan sọ wipe
awọn ko fẹ ni ipin kankan ninu iwadi yi mọ. Lẹhin
ijiroro pẹlu wọn ati awọn oluwadi, a le yọ ohun ti a
gba lati ẹya wọn kuro ninu işẹ yi.
A ko ni erogba wipe a o ri ohun kan amuşẹşọ ninu
iwadi yi. Amọ awọn oluwadi miran le lo ilana yi lati mu
ọgbọn titun tabi imọ jade, ti yio jẹki a ni imọ
ti o peye si lori aisan ati awọn ohun ti o nfa wọn. Ero wa ni wipe,
ilana HapMap yi yio jẹ ohun anfani fun gbogbo enia lapapọ,
amọ o şeşe wipe ki o pẹ diẹ ki a to ri anfani yi.
|