HapMap Project logo
Asepọ HapMap ti Gbogbo Agbaye
 

Ibusọ | Nipa Asepọ | Esi | Itẹjade | Tutorial |

中文 | English | Français | 日本 | Yoruba
About the HapMap
Kinni HapMap?
Orisun iwon-Jiini (Haplotypes)
Anfani
Awon Eya ti a ti se iwadi
Majeobaje
Iwe Idarapo mo iwadi
Community Advisory Groups(CAG)
Ilana Agbekale Esi Iwadi
Ilana lilo Esi Iwadi
Guidelines For Referring to HapMap Populations
 
Project Information
Nipa Asepọ
Itẹjade HapMap
HapMap Tutorial
Olukọwesi HapMap
Alajọşe HapMap
Ẹda oju iwe yi ni ilu Japani
 
Useful Links
HapMap Project Press Release
NHGRI HapMap Page
NCBI Variation Database (dbSNP)
Japanese SNP Database (JSNP)
Ara awọn ẹya wo ni a ti nşe iwadi yi

Ilana HapMap bẹrẹ pẹlu ẹya ara lati ara enia dudu, kọọra ati oyinbo. Ni apapọ, awọn ẹya yi yio jẹ ki a le şe awari gbogbo iwọn-jiini ti nbẹ ninu awọn enia agbaye. [Ẹ tẹ ikanna yin mọ ibiyi lati mọ ohun ti HapMap nşe]

Nitori ipilẹsẹ enia, a mọ wipe awọn iwọn-jiini orisi kanna yio wọpọ larin awa ọmọ enia.[Ẹ wo orisun iwọn-Jiini] Amọ orisi kan pato le pọ ninu ẹya kan ju ekeji lọ, awọn iwọn-jiini ti o si titun ju le wa ninu ẹya kanşoşo. Lati le ri ilana ti o peye ju, a ni lati lo siniipu-alapẹrẹ lati ẹya ọmọ enia melo kan. Eleyi yio si ran awọn oluwadi lọwọ lati le mọ ipa ti ajogunba nko ninu aisan ti o wọpọ tabi ti ko wọpọ lati ẹya si ẹya.

A o lo ẹya ara ti a npe ni DNA lati ara awọn enia igba ati adọrin. Awọn Yoruba ti ngbe Ibadan, Nigeria yio pese ẹya ara lati ọwọ mọlẹbi ọgbọn. Itumọ mọlẹbi ti a o si lo fun iwadi yi jẹ obi meji ati ọmọ kan, eyiti awọn onimọ-ijinlẹ n pe ni tirio (trio). Ni ilu Japani, a o lo enia marundinladọfa, lati agbegbe Tokyo. Ni Şhaina, a o wa iye enia kanna lati agbegbe Beijing, Ni ilu Amerika, a o lo mọlẹbi (iru ti Yoruba) ọgbọn ti iran wọn wa lati ariwa ati iwọ-orun ilu oyinbo, ti ẹjẹ wọn si wa ni ipamọ labẹ akoso Centre dÕEtude du Polymorphisme Humani (CEPH) lati ọdun 1980.

Ile-işẹ Coriell ni a o toju awọn ẹya wọnyi si [Ẹ wo http://locus.umdnj.edu/nigms fun alaye.] Nibẹ ni awọn oluwadi gbogbo ti o ba fẹ lo awọn ẹya ara yi yio lọ, pelu asẹ lati ọwọ awọn igbimọ ti nşe alabojuto olukopa ninu iwadi. A ko ni gba imọ tabi oye kankan ti yio jẹ ki awọn ti o ba darapọ mọ işẹ yi di mimọ. Amọ a o da awọn ẹya enia ti awọn ohun imulo yi ti wa mọ, boya Yoruba ni o, tabi ti ọmọ ilẹ Japani. Eleyi mu ọrọ idabobo olukopa ati awọn ilu ti wọn ti wa lọwọ. [ Ẹ wo ilana ti a gbe kalẹ lati daabobo awọn olukopa ati Ilana bi a ti şe gbọdọ ma darukọ awọn ilu ati ẹya enia ti a gba jiini lara wọn. ]

Lati le mọ boya şi şe iwadi lori awọn ẹya ju mẹrin ti a fi bẹrẹ yi yio ran wa lọwọ, a o şe iwadi ranpẹ lara awọn ẹya bi melo miran.


Ibusọ | Nipa Asepọ | Esi | Itẹjade | Tutorial |
Ti ẹ ba ni ibere tabi asọsi, ẹ le kan si help@hapmap.org