|
Ibaşepọ ere ifẹ ati itan isẹdalẹ ẹda ni
o şe afọwọfa iwọn-jiini.
Ti a ba yọ awọn akasu-jiini ti njẹ ki a di
ọmọkunri tabi ọmọbinrin, mejimeji ni akaşu-jiini
inu ara, ọkan lati ikori baba, ekeji lati ọdọ ti iya
ẹni. Amọ ki i şe wipe awọn jiini a kan ti ara baba tabi
iya si ara ọmọ lai yipada. Rara o, wọn a ma lọmọ
ara wọn, wọn a si ma parada debi wipe akaşu-jiini ti yio wa
lara ọmọ yio ni diẹ lati ọdọ baba, diẹ lati
ọdọ iya. Iru jiini titun ti o şẹlẹ yi ni a o fi
fun ọmọ ẹni. Nigbati asiko ba dẹ to, tirẹ
na yio yira pada.
 |
|
Aworan Kinni: Aworan yi fi bi awọn jiini şe nparada han wa. Ti
iyatọ 'X' ba wa, ti o toro mọ aisan kan, a o ri wipe iru aisan
bẹ a wọpọ lara awọn ti o ba jogun jiini yi, ju eniti ko
ni iru rẹ rara. A o ri wipe, awọn siniipu orişirişi ni o
wa nitosi 'X' ti a le fi da a mọ.
|
Ti a ba wo iran diran, a o ri wipe iwọn akaşu-jiini a ma parada
lọpọlọpọ igba bi awọn eniyan ba ti şe
nfẹ ara wọn, ti wọn si bi si, ti wọn npọ si. A si le ri
awọn enia bi melo kan ti gẹẹgẹ iwọn jiini
wọn fi arajọra (Aworan Kinni). Iru awọn iwọn jiini
bawọn wọnyi ko parada lati iran de iran niyẹn.
Awọn iwọn-jiini iru wọnyi ni awọn
ọjọgbọn ma nlo lati şe iwadi aisan.
Gbogbo ohun ti a mọ fi
apẹrẹ han wipe ilẹ awa enia dudu ni orisun gbogbo awọn
enia to wa ni agbaye. Ni iwọn igba ti eleyi sẹlẹ ko ti ju
ẹgbẹgbẹrun ati abọ ọdun lọ. Nitori wipe ko
pẹ pupọ ti awa eniyan gborisọ, iyatọ ti o wa larin wa
ko pọ rara. Siwaju si, gbogbo awọn ẹya enia ti
wọn tan ka si ilẹ okere ko diẹ ninu iyatọ ti o wa ninu
jiini orisun wọn ni. Nitori idi eyi, ki i şe gbogbo iyatọ ti o
wa ninu jiini awọn enia dudu ni a nri ninu ti oyinbo-alawọ-funfun.
Bakanna, awọn iwọn-jiini ti a nri lara awọn ẹya miran
jẹ diẹ lara iru eyiti a nri lara awọn enia dudu.
Iwọn-jiini awọn ti ko ki nşe enia dudu a ma gun ju ti
awọn enia dudu lọ.
Bi awọn ẹya enia se
pin kakiri gbogbo agbaye, iye iwọn-jiini ti a n ri bẹrẹ si
yatọ lati ibikan si omiran nipasẹ ayan (chance), ilana aye (natural selection) ati bẹẹbẹ lọ.
Nitori idi eyi, a le ri iru iwọn-jiini kan ni sakani kan, ki o ma si si
ni sakani keji, paapa ti awọn sakani wọnyi ba jina si ara
wọn, ti ko si si aye ibalopọ fun wọn. Siwaju si, iyatọ
titun le sẹlẹ larin awọn sakani wọnyi lẹhin ti
wọn ba pinya. Eleyi a si jẹki iwọn-jiini titun gborisọ
ninu awọn ẹya wọnyi laisi anfani wipe ki wọn tan ka
lọ si arin awọn ẹya miran.
|