HapMap Project logo
Asepọ HapMap ti Gbogbo Agbaye
 

Ibusọ | Nipa Asepọ | Esi | Itẹjade | Tutorial |

中文 | English | Français | 日本 | Yoruba
About the HapMap
Kinni HapMap?
Orisun iwon-Jiini (Haplotypes)
Anfani
Awon Eya ti a ti se iwadi
Majeobaje
Iwe Idarapo mo iwadi
Community Advisory Groups(CAG)
Ilana Agbekale Esi Iwadi
Ilana lilo Esi Iwadi
Guidelines For Referring to HapMap Populations
 
Project Information
Ibusọ
HapMap Esi
Olukọwesi HapMap
Alajọşe HapMap
Ẹda oju iwe yi ni ilu Japani
 
Useful Links
HapMap Project Press Release
NHGRI HapMap Page
NCBI Variation Database (dbSNP)
Japanese SNP Database (JSNP)
Nipa Asepọ HapMap ti Gbogbo Agbaye

Iwadi HapMap jẹ ilana titun ti a o fi şe awari lori awọn ẹya ara ti a npe ni Jiini(Gene), eyiti oun dari bi awa ọmọ eniyan ti jọra tabi ti a fi yatọ si ara wa. Ilana titun yi, yio jẹ ki a le şiwadi ti o peye lori Jiini, paapa, nipa ọna ti Jiini onikaluku fi yatọ si ara wọn nipasẹ nini aisan tabi ilera ati bi ogun şe ba wa lara mu si. Awọn Ọjọgbọn lati orilẹ-ede Japani (Japan), Şhaina(China), Kanada (Canada), Amerika (United States), Ilu-Ọba(United Kingdom) ati orilẹ-ede wa Naijiria ni wọn jọ nşe iwadi yi [Ẹ tẹ ikaana mọ ibi yi lati le ni imọ si nipa awọn alaşepọ iwadi yi]. Gbogbo abajade iwadi yi ni a o fi han gbogbo agbaye, ti ko ni si alanikanje kankan ninu rẹ.

Idi ti a şe gbe iwadi HapMap kalẹ ni lati şe ilana titun ti a le fi yẹ ohun ti o wa ninu ẹjẹ ọmọ eniyan ti o ndari ajogunba; eyiti a npe ni Jiini, tabi ti awọn oloyinbo npe ni Gene.[Ẹ tẹ ikaana mọ ibi yi lati le ni imọ si nipa HapMap yi] Nipa pipese esi iwadi yi fun mutunmuwa, iwadi yi yio jẹ ohun anfani nla fun awọn Ọjogbon ti wọn şiwadi lori ọna ti Jiini şe ndarapọ mọ aisan, ilera, tabi bi ogun orişirişi şe nba eniyan lara mu ati bẹ bẹ lọ [Ẹ tẹ ikaana mọ ibi yi lati le ni imọ si nipa bi iwadi yi şe le şe anfani fun ilera gbogbo agbaye]. Ni igbeşẹ kinni iwadi yi, a n gba ẹya lati ara awọn eya eniyan merin ti wọn jẹ eniyan dudu, oyinbo ati kọọra. Lọwọlọwọ bayi, a njiroro pẹlu awọn eniyan wọnyi lori awọn ọrọ majẹobajẹ, eleyi si nfun wa ni imọ ti o peye lori ọna ti o tọ lati ma şe iru iwadi bayi.

Ijọba ati ile-işẹ aladani ni awọn orilẹ-ede mẹfa ni wọn jọ nşe alagbekalẹ iwadi yi. Ẹ le ri esi iwadi yi fasile fun lilo laisi iyọnu kankan ni [Ẹ tẹ ikaana mọ ibi yi lati ri ilana bi a ti se n lo esi iwadi yi.] Larin ọjọ kẹta si ọkan-dinlọgbọn oşu kẹwa Ọdun 2002(http://genome.gov/10005336) ni a bẹrẹ eto yi. A si lero wipe yio gba ọdun mẹta gbako.



Ibusọ | Nipa Asepọ | Esi | Itẹjade | Tutorial |
Ti ẹ ba ni ibere tabi asọsi, ẹ le kan si hapmap-help@ncbi.nlm.nih.gov